Yoruba bọ, wọn ni yinni yinni ki ẹni ṣe mii, eyi lo difa fun Aarẹ Bola Tinubu ti o fi ami ẹyẹ MON dawọn ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lọla lẹyin ti wọn wọ ipele aṣekagba idije Afcon 2023 lorilẹede Ivory Coast.
Bo tilẹ jẹ pe Ivory Coast to gbalejo idije naa gbo ewuro soju ikọ agbabọọlu Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba ọhun lẹyin ti wọn lu Super Eagles pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan, Aarẹ Tinubu ni wọn fakọyọ ninu idije naa.
Ijọba tun fun wọn ni ile fulaati kọọkan ati ilẹ niluu Abuja.
Ni ile ijọba orilẹede Naijiria ni aarẹ ti gbawọn ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lalejo ni ọjọ Iṣẹgun niluu Abuja.
Gbogbo ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles atawọn akọnimọọgba wọn lo wa nibi ayẹyẹ naa.
Ninu atẹajde ti o fi sita lẹyin ayẹyẹ ifi ami ẹyẹ danilọla naa, Aarẹ Tinubu ki gbogbo agbabọọlu Super Eagles, akọnimọọgba wọn, Jose Peseiro atawọn iṣọmọgbe rẹ wi pe wọn ku iṣẹ takun takun ti wọn ṣe ninu idije Afcon 2023.
Aarẹ gboṣuba fun wọn lori bi wọn ṣe fakọyọ lati ipele kan si omiran ti wọn fi de ipele aṣekagba idije ọhun.
Ẹwẹ, Aarẹ Tinubu ti kọkọ rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ma inu jẹ pe Naijiria padanu lati gba ife ẹyẹ Afcon 2023 wale.
Tinubu ni Naijiria gbegba oroke ninu ọkan awọn ọmọ ilẹ Africa ati gbogbo agbaye pẹlu bi wọn ti gbabọọlu tọkan tọkan ni idije Afcon 2023.
”Ẹ ma ṣe jẹ ki ohun to ṣẹlẹ ni Ivory Coast ba wa ninu jẹ, amọ, ẹ jẹ ki rii gẹgẹ bi ipenija lati tubọ tẹpa mọ iṣẹ.
Orilẹede nla ni a jẹ eyi ti ireti, ifẹ ti kii saarẹ ati iṣẹ takun takun so pọ.
Si gbogbo awọn ọdọ ọmọ Naijiria ti wọn n lo ẹbun wọn ni awujọ ti wọn wa, ati awọn ti wọn n gba bọọlu lori yẹpẹ, ẹ le di akọni fun wa lọla, ẹ maa kaarẹ.
Ijọba mi wa nibi lati mu ala yin ṣẹ,” Tinubu lo sọ bẹẹ.